7 Iwọ ni ibi ipamọ́ mi: iwọ o pa mi mọ́ kuro ninu iṣẹ́; iwọ o fi orin igbala yi mi ka kiri.
8 Emi o fi ẹsẹ̀ rẹ le ọ̀na, emi o si kọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ o rìn: emi o ma fi oju mi tọ́ ọ.
9 Ki ẹnyin ki o máṣe dabi ẹṣin tabi ibaka, ti kò ni iyè ninu: ẹnu ẹniti a kò le ṣe aifi ijanu bọ̀, ki nwọn ki o má ba sunmọ ọ.
10 Ọ̀pọ ikãnu ni yio wà fun enia buburu: ṣugbọn ẹniti o ba gbẹkẹle Oluwa, ãnu ni yio yi i ka kiri.
11 Ki inu nyin ki o dùn niti Oluwa, ẹ si ma yọ̀, ẹnyin olododo; ẹ si ma kọrin fun ayọ̀, gbogbo ẹnyin ti aiya nyin duro ṣinṣin.