5 Ki nwọn ki o dabi iyangbo niwaju afẹfẹ: ki angeli Oluwa ki o ma le wọn.
6 Ki ọ̀na wọn ki o ṣokunkun ki o si ma yọ́; ki angeli Oluwa ki o si ma lepa wọn.
7 Nitori pe, li ainidi ni nwọn dẹ àwọn wọn silẹ fun mi, nwọn wà iho silẹ fun ọkàn mi li ainidi.
8 Ki iparun ki o wá si ori rẹ̀ li ojiji; àwọn rẹ̀ ti o dẹ, ki o mu on tikararẹ̀: iparun na ni ki o ṣubu si.
9 Ọkàn mi yio si ma yọ̀ niti Oluwa: yio si ma yọ̀ ninu igbala rẹ̀.
10 Gbogbo egungun mi ni yio wipe, Oluwa, tali o dabi iwọ, ti ngbà talaka lọwọ awọn ti o lagbara jù u lọ, ani talaka ati alaini lọwọ ẹniti nfi ṣe ikogun?
11 Awọn ẹlẹri eke dide; nwọn mbi mi li ohun ti emi kò mọ̀.