8 Ki iparun ki o wá si ori rẹ̀ li ojiji; àwọn rẹ̀ ti o dẹ, ki o mu on tikararẹ̀: iparun na ni ki o ṣubu si.
9 Ọkàn mi yio si ma yọ̀ niti Oluwa: yio si ma yọ̀ ninu igbala rẹ̀.
10 Gbogbo egungun mi ni yio wipe, Oluwa, tali o dabi iwọ, ti ngbà talaka lọwọ awọn ti o lagbara jù u lọ, ani talaka ati alaini lọwọ ẹniti nfi ṣe ikogun?
11 Awọn ẹlẹri eke dide; nwọn mbi mi li ohun ti emi kò mọ̀.
12 Nwọn fi buburu san ore fun mi, lati sọ ọkàn mi di ofo.
13 Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, nigbati ara wọn kò dá, aṣọ àwẹ li aṣọ mi: mo fi àwẹ rẹ̀ ọkàn mi silẹ; adura mi si pada si mi li aiya.
14 Emi ṣe ara mi bi ẹnipe ọrẹ tabi arakunrin mi tilẹ ni: emi fi ibinujẹ tẹriba, bi ẹniti nṣọ̀fọ iya rẹ̀.