1 MÁṢE ikanra nitori awọn oluṣe-buburu, ki iwọ ki o máṣe ilara nitori awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.
2 Nitori ti a o ke wọn lulẹ laipẹ bi koriko, nwọn o si rọ bi eweko tutù.
3 Gbẹkẹle Oluwa, ki o si ma ṣe rere; ma gbe ilẹ na, ki o si ma huwa otitọ.
4 Ṣe inu-didùn si Oluwa pẹlu, on o si fi ifẹ inu rẹ̀ fun ọ.
5 Fi ọ̀na rẹ̀ le Oluwa lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; on o si mu u ṣẹ.