16 Ohun diẹ ti olododo ni sanju ọrọ̀ ọ̀pọ enia buburu.
17 Nitoriti a o ṣẹ́ apa awọn enia buburu: ṣugbọn Oluwa di olododo mu.
18 Oluwa mọ̀ ọjọ ẹni iduro-ṣinṣin: ati ilẹ-ini wọn yio wà lailai.
19 Oju kì yio tì wọn ni igba ibi: ati li ọjọ ìyan a o tẹ́ wọn lọrun.
20 Ṣugbọn awọn enia buburu yio ṣegbe, awọn ọta Oluwa yio dabi ẹwà oko-tutu: nwọn o run; ẹ̃fin ni nwọn o run si.
21 Awọn enia buburu wín, nwọn kò si pada san: ṣugbọn olododo a ma ṣãnu, a si ma fi funni.
22 Nitoriti awọn ẹni-ibukún rẹ̀ ni yio jogun aiye; awọn ẹni-egún rẹ̀ li a o ke kuro.