22 Nitoriti awọn ẹni-ibukún rẹ̀ ni yio jogun aiye; awọn ẹni-egún rẹ̀ li a o ke kuro.
23 A ṣe ìlana ẹsẹ enia lati ọwọ Oluwa wá: o si ṣe inu didùn si ọ̀na rẹ̀.
24 Bi o tilẹ ṣubu, a kì yio ta a nù kuro patapata; nitoriti Oluwa di ọwọ rẹ̀ mu.
25 Emi ti wà li ewe, emi si dagba; emi kò ti iri ki a kọ̀ olododo silẹ, tabi ki iru-ọmọ rẹ̀ ki o ma ṣagbe onjẹ.
26 Alãnu li on nigbagbogbo, a ma wín ni: a si ma busi i fun iru-ọmọ rẹ̀.
27 Kuro ninu ibi ki o si ma ṣe rere; ki o si ma joko lailai.
28 Nitoriti Oluwa fẹ idajọ, kò si kọ̀ awọn enia mimọ́ rẹ̀ silẹ; a si pa wọn mọ́ lailai: ṣugbọn iru-ọmọ awọn enia buburu li a o ke kuro.