37 Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wò ẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkunrin na.
38 Ṣugbọn awọn alarekọja li a o parun pọ̀; iran awọn enia buburu li a o ké kuro.
39 Ṣugbọn lati ọwọ Oluwa wá ni igbala awọn olododo; on li àbo wọn ni igba ipọnju.
40 Oluwa yio si ràn wọn lọwọ, yio si gbà wọn, yio si gbà wọn lọwọ enia buburu, yio si gbà wọn la, nitoriti nwọn gbẹkẹle e.