7 Iwọ simi ninu Oluwa, ki o si fi sũru duro dè e; máṣe ikanra nitori ẹniti o nri rere li ọ̀na rẹ̀, nitori ọkunrin na ti o nmu èro buburu ṣẹ.
8 Dakẹ inu-bibi, ki o si kọ̀ ikannu silẹ: máṣe ikanra, ki o má ba ṣe buburu pẹlu.
9 Nitori ti a o ke awọn oluṣe-buburu kuro: ṣugbọn awọn ti o duro de Oluwa ni yio jogun aiye.
10 Nitori pe nigba diẹ, awọn enia buburu kì yio si: nitotọ iwọ o fi ara balẹ wò ipò rẹ̀, kì yio si si.
11 Ṣugbọn awọn ọlọkàn-tutù ni yio jogun aiye; nwọn o si ma ṣe inu didùn ninu ọ̀pọlọpọ alafia.
12 Enia buburu di rikiṣi si olõtọ, o si pa ehin rẹ̀ keke si i lara.
13 Oluwa yio rẹrin rẹ̀; nitori ti o ri pe, ọjọ rẹ̀ mbọ̀.