1 OLUWA, máṣe ba mi wi ninu ibinu rẹ: bẹ̃ni ki o máṣe nà mi ni gbigbona ibinujẹ rẹ.
2 Nitori ti ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin, ọwọ rẹ si kì mi wọ̀ mọlẹ.
3 Kò si ibi yíyè li ara mi nitori ibinu rẹ; bẹ̃ni kò si alafia li egungun mi nitori ẹ̀ṣẹ mi.
4 Nitori ti ẹbi ẹ̀ṣẹ mi bori mi mọlẹ, bi ẹrù wuwo, o wuwo jù fun mi.
5 Ọgbẹ mi nrùn, o si dibajẹ nitori were mi.
6 Emi njowere; ori mi tẹ̀ ba gidigidi; emi nṣọ̀fọ kiri li gbogbo ọjọ.