13 Ṣugbọn emi, bi aditi, emi kò gbọ́; ati bi odi ti kò ya ẹnu rẹ̀.
14 Bẹ̃ni mo dabi ọkunrin ti kò gbọ́ran, ati li ẹnu ẹniti iyàn kò si.
15 Nitori, Oluwa, iwọ li emi duro dè, iwọ o gbọ́, Oluwa Ọlọrun mi.
16 Nitori ti mo wipe, Gbohùn mi, ki nwọn ki o má ba yọ̀ mi; nigbati ẹsẹ mi ba yọ́, nwọn o ma gbé ara wọn ga si mi.
17 Emi ti mura ati ṣubu, ikãnu mi si mbẹ nigbagbogbo niwaju mi.
18 Nitori ti emi o jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi; emi o kãnu nitori ẹ̀ṣẹ mi.
19 Ṣugbọn ara yá awọn ọta mi, ara wọn le; awọn ti o korira mi lodi npọ̀ si i.