18 Nitori ti emi o jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi; emi o kãnu nitori ẹ̀ṣẹ mi.
19 Ṣugbọn ara yá awọn ọta mi, ara wọn le; awọn ti o korira mi lodi npọ̀ si i.
20 Awọn ti o si nfi buburu san rere li ọta mi; nitori emi ntọpa ohun ti iṣe rere.
21 Oluwa, máṣe kọ̀ mi silẹ; Ọlọrun mi, máṣe jina si mi.
22 Yara lati ran mi lọwọ, Oluwa igbala mi.