1 MO ni, emi o ma kiyesi ọ̀na mi, ki emi ki o má fi ahọn mi ṣẹ̀; emi o fi ijanu ko ara mi li ẹnu nigbati enia buburu ba mbẹ niwaju mi.
2 Mo fi idakẹ yadi, mo tilẹ pa ẹnu mi mọ́ kuro li ọ̀rọ rere: ibinujẹ mi si ru soke.
3 Aiya mi gbona ninu mi, nigbati emi nronu, ina ràn: nigbana ni mo fi ahọn mi sọ̀rọ.
4 Oluwa, jẹ ki emi ki o mọ̀ opin mi ati ìwọn ọjọ mi, bi o ti ri; ki emi ki o le mọ̀ ìgbà ti mo ni nihin.
5 Kiyesi i, iwọ ti sọ ọjọ mi dabi ibu atẹlẹwọ; ọjọ ori mi si dabi asan niwaju rẹ: nitõtọ olukuluku enia ninu ijoko rere rẹ̀ asan ni patapata.
6 Nitotọ li àworan asan li enia gbogbo nrìn: nitotọ ni nwọn nyọ ara wọn lẹnu li asan: o nkó ọrọ̀ jọ, kò si mọ̀ ẹniti yio kó wọn lọ.
7 Njẹ nisisiyi, Oluwa kini mo duro de? ireti mi mbẹ li ọdọ rẹ.