6 Nitotọ li àworan asan li enia gbogbo nrìn: nitotọ ni nwọn nyọ ara wọn lẹnu li asan: o nkó ọrọ̀ jọ, kò si mọ̀ ẹniti yio kó wọn lọ.
7 Njẹ nisisiyi, Oluwa kini mo duro de? ireti mi mbẹ li ọdọ rẹ.
8 Gbà mi ninu irekọja mi gbogbo: ki o má si sọ mi di ẹni ẹ̀gan awọn enia buburu.
9 Mo yadi, emi kò ya ẹnu mi; nitoripe iwọ li o ṣe e.
10 Mu ọwọ ìna rẹ kuro li ara mi: emi ṣegbe tan nipa ìja ọwọ rẹ.
11 Nigbati iwọ ba fi ibawi kilọ fun enia nitori ẹ̀ṣẹ, iwọ a ṣe ẹwà rẹ̀ a parun bi kòkoro aṣọ: nitõtọ asan li enia gbogbo.
12 Oluwa, gbọ́ adura mi, ki o si fi eti si ẹkún mi, ki o máṣe pa ẹnu rẹ mọ́ si omije mi: nitori alejo li emi lọdọ rẹ, ati atipo, bi gbogbo awọn baba mi ti ri.