1 ẸNYIN enia, gbogbo ẹ ṣapẹ; ẹ fi ohùn ayọ̀ hó ihó iṣẹgun si Ọlọrun.
2 Nitori Oluwa Ọga-ogo li ẹ̀ru; on li ọba nla lori ilẹ-aiye gbogbo.
3 On ni yio ṣẹ́ awọn enia labẹ wa, ati awọn orilẹ-ède li atẹlẹsẹ wa.
4 On ni yio yàn ilẹ-ini wa fun wa, ọlá Jakobu, ẹniti o fẹ.
5 Ọlọrun gòke lọ ti on ti ariwo, Oluwa, ti on ti iró ipè.