4 On ni yio yàn ilẹ-ini wa fun wa, ọlá Jakobu, ẹniti o fẹ.
5 Ọlọrun gòke lọ ti on ti ariwo, Oluwa, ti on ti iró ipè.
6 Ẹ kọrin iyìn si Ọlọrun, ẹ kọrin iyìn: ẹ kọrin iyìn si Ọba wa, ẹ kọrin iyìn.
7 Nitori Ọlọrun li Ọba gbogbo aiye: ẹ fi oye kọrin iyìn.
8 Ọlọrun jọba awọn keferi: Ọlọrun joko lori itẹ ìwa-mimọ́ rẹ̀.
9 Awọn alade awọn enia kó ara wọn jọ, ani awọn enia Ọlọrun Abrahamu: nitori asà aiye ti Ọlọrun ni: on li a gbe leke jọjọ.