1 ẸGBỌ́ eyi, gbogbo enia; ẹ fi eti si i, gbogbo ẹnyin araiye:
2 Ati awọn ọmọ-ẹhin ati awọn ẹni-ọlá, awọn ọlọrọ̀ ati awọn talaka pẹlu.
3 Ẹnu mi yio sọ̀rọ ọgbọ́n, ati iṣaro aiya mi yio jẹ oye.
4 Emi o dẹ eti mi silẹ si owe: emi o ṣi ọ̀rọ ìkọkọ mi silẹ loju okùn dùru.