13 Ipa ọ̀na wọn yi ni igbẹkẹle wọn: ọ̀rọ wọn si tọ́ li oju awọn ọmọ wọn.
14 Bi agutan li a ntẹ wọn si isa-okú: ikú yio jẹun lara wọn; ẹni diduro-ṣinṣin ni yio jọba wọn li owurọ; ẹwà wọn yio si rẹ̀ kuro, isa-okú si ni ibugbe wọn.
15 Ṣugbọn Ọlọrun ni yio rà ọkàn mi lọwọ isa-okú: nitoripe on o gbà mi.
16 Iwọ máṣe bẹ̀ru, nitori ẹnikan di ọlọrọ̀, nitori iyìn ile rẹ̀ npọ̀ si i.
17 Nitoripe, igbati o ba kú, kì yio kó ohun kan lọ: ogo rẹ̀ kì yio sọkalẹ tọ̀ ọ lẹhin lọ.
18 Nigbati o wà lãye bi o tilẹ nsure fun ọkàn ara rẹ̀: ti awọn enia nyìn ọ, nigbati iwọ nṣe rere fun ara rẹ.
19 Ọkàn yio lọ si ọdọ iran awọn baba rẹ̀; nwọn kì yio ri imọlẹ lailai.