8 Nitori irapada ọkàn wọn iyebiye ni, o si dẹkun lailai:
9 Nipe ki o fi mã wà lailai, ki o má ṣe ri isa-okú.
10 Nitori o nri pe awọn ọlọgbọ́n nkú, bẹ̃li aṣiwere ati ẹranko enia nṣegbe, nwọn si nfi ọrọ̀ wọn silẹ fun ẹlomiran.
11 Ìro inu wọn ni, ki ile wọn ki o pẹ titi lai, ati ibujoko wọn lati irandiran; nwọn sọ ilẹ wọn ní orukọ ara wọn.
12 Ṣugbọn enia ti o wà ninu ọlá kò duro pẹ: o dabi ẹranko ti o ṣegbé.
13 Ipa ọ̀na wọn yi ni igbẹkẹle wọn: ọ̀rọ wọn si tọ́ li oju awọn ọmọ wọn.
14 Bi agutan li a ntẹ wọn si isa-okú: ikú yio jẹun lara wọn; ẹni diduro-ṣinṣin ni yio jọba wọn li owurọ; ẹwà wọn yio si rẹ̀ kuro, isa-okú si ni ibugbe wọn.