1 FI eti si ọ̀rọ mi, Oluwa, kiyesi aroye mi.
2 Fi eti si ohùn ẹkún mi, Ọba mi, ati Ọlọrun mi: nitoripe ọdọ rẹ li emi o ma gbadura si.
3 Ohùn mi ni iwọ o gbọ́ li owurọ, Oluwa, li owurọ li emi o gbà adura mi si ọ, emi o si ma wòke.
4 Nitori ti iwọ kì iṣe Ọlọrun ti iṣe inu-didùn si ìwa buburu: bẹ̃ni ibi kò le ba ọ gbe.
5 Awọn agberaga kì yio le duro niwaju rẹ: iwọ korira gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.
6 Iwọ o pa awọn ti nṣe eke run; Oluwa yio korira awọn ẹni-ẹ̀jẹ ati ẹni-ẹ̀tan.