4 Nitori ti iwọ kì iṣe Ọlọrun ti iṣe inu-didùn si ìwa buburu: bẹ̃ni ibi kò le ba ọ gbe.
5 Awọn agberaga kì yio le duro niwaju rẹ: iwọ korira gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.
6 Iwọ o pa awọn ti nṣe eke run; Oluwa yio korira awọn ẹni-ẹ̀jẹ ati ẹni-ẹ̀tan.
7 Ṣugbọn bi o ṣe ti emi, emi o wá sinu ile rẹ li ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ: ninu ẹ̀ru rẹ li emi o tẹriba si iha tempili mimọ́ rẹ.
8 Tọ́ mi, Oluwa, ninu ododo rẹ, nitori awọn ọta mi: mu ọ̀na rẹ tọ́ tàra niwaju mi.
9 Nitori ti otitọ kan kò si li ẹnu ẹnikẹni wọn; ikakika ni iha inu wọn; isa-okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi npọ́nni.
10 Iwọ da wọn lẹbi, Ọlọrun; ki nwọn ki o ti ipa ìmọ ara wọn ṣubu; já wọn kuro nitori ọ̀pọlọpọ irekọja wọn; nitori ti nwọn ti ṣọ̀tẹ si ọ.