2 Wẹ̀ mi li awẹmọ́ kuro ninu aiṣedede mi, ki o si wẹ̀ mi nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi.
3 Nitori ti mo jẹwọ irekọja mi: nigbagbogbo li ẹ̀ṣẹ mi si mbẹ niwaju mi.
4 Iwọ, iwọ nikanṣoṣo ni mo ṣẹ̀ si, ti mo ṣe buburu yi niwaju rẹ: ki a le da ọ lare, nigbati iwọ ba nsọ̀rọ, ki ara rẹ ki o le mọ́, nigbati iwọ ba nṣe idajọ.
5 Kiyesi i, ninu aiṣedede li a gbe bi mi: ati ninu ẹ̀ṣẹ ni iya mi si loyun mi.
6 Kiyesi i, iwọ fẹ otitọ ni inu: ati niha ìkọkọ ni iwọ o mu mi mọ̀ ọgbọ́n.
7 Fi ewe-hissopu fọ̀ mi, emi o si mọ́: wẹ̀ mi, emi o si fún jù ẹ̀gbọn-owu lọ.
8 Mu mi gbọ́ ayọ̀ ati inu didùn; ki awọn egungun ti iwọ ti rún ki o le ma yọ̀.