4 Oró wọn dabi oró ejò: nwọn dabi aditi ejò pamọlẹ ti o di ara rẹ̀ li eti;
5 Ti kò fẹ igbọ́ ohùn awọn atuniloju, bi o ti wù ki o ma fi ọgbọ́n ṣe ituju to.
6 Ká wọn li ehin, Ọlọrun, li ẹnu wọn: ká ọ̀gan awọn ọmọ kiniun nì, Oluwa.
7 Ki nwọn ki o yọ́ danu bi omi ti nṣàn nigbagbogbo: nigbati o ba fa ọrun lati tafà rẹ̀, ki nwọn ki o dabi ẹnipe a ke wọn ni ijanja.
8 Bi igbín ti a tẹ̀ rẹ́ ti o si ṣegbe: bi iṣẹnu obinrin, bẹ̃ni ki nwọn ki o má ṣe ri õrùn.
9 Ki ikoko nyin ki o to mọ̀ igbona ẹgún, iba tutu iba ma jo, yio fi iji gbá wọn lọ.
10 Olododo yio yọ̀ nigbati o ba ri ẹsan na: yio si wẹ̀ ẹsẹ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ awọn enia buburu.