6 Ká wọn li ehin, Ọlọrun, li ẹnu wọn: ká ọ̀gan awọn ọmọ kiniun nì, Oluwa.
7 Ki nwọn ki o yọ́ danu bi omi ti nṣàn nigbagbogbo: nigbati o ba fa ọrun lati tafà rẹ̀, ki nwọn ki o dabi ẹnipe a ke wọn ni ijanja.
8 Bi igbín ti a tẹ̀ rẹ́ ti o si ṣegbe: bi iṣẹnu obinrin, bẹ̃ni ki nwọn ki o má ṣe ri õrùn.
9 Ki ikoko nyin ki o to mọ̀ igbona ẹgún, iba tutu iba ma jo, yio fi iji gbá wọn lọ.
10 Olododo yio yọ̀ nigbati o ba ri ẹsan na: yio si wẹ̀ ẹsẹ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ awọn enia buburu.
11 Bẹ̃li enia o si wipe, Lõtọ, ère mbẹ fun olododo: lõtọ, on li Ọlọrun ti o nṣe idajọ ni aiye.