1 ỌLỌRUN mi, gbà mi lọwọ awọn ọta mi: dãbobo mi lọwọ awọn ti o dide si mi.
2 Gbà mi lọwọ awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ, ki o si gbà mi silẹ lọwọ awọn enia-ẹ̀jẹ.
3 Sa kiyesi i, nwọn ba ni buba fun ọkàn mi, awọn alagbara pejọ si mi; kì iṣe nitori irekọja mi, tabi nitori ẹ̀ṣẹ mi, Oluwa.
4 Nwọn sure, nwọn mura li aiṣẹ mi: dide lati pade mi, ki o si kiyesi i.
5 Nitorina iwọ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, jí lati bẹ̀ gbogbo awọn keferi wò; máṣe ṣãnu fun olurekọja buburu wọnni.
6 Nwọn pada li aṣalẹ: nwọn npariwo bi ajá, nwọn nrìn yi ilu na ka.
7 Kiyesi i, nwọn nfi ẹnu wọn gùfẹ jade: idà wà li ète wọn: nitoriti nwọn nwipe, tali o gbọ́?