4 Nwọn sure, nwọn mura li aiṣẹ mi: dide lati pade mi, ki o si kiyesi i.
5 Nitorina iwọ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, jí lati bẹ̀ gbogbo awọn keferi wò; máṣe ṣãnu fun olurekọja buburu wọnni.
6 Nwọn pada li aṣalẹ: nwọn npariwo bi ajá, nwọn nrìn yi ilu na ka.
7 Kiyesi i, nwọn nfi ẹnu wọn gùfẹ jade: idà wà li ète wọn: nitoriti nwọn nwipe, tali o gbọ́?
8 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio rẹrin wọn: iwọ ni yio yọṣuti si gbogbo awọn keferi.
9 Agbara rẹ̀ li emi o duro tì: nitori Ọlọrun li àbo mi.
10 Ọlọrun ãnu mi ni yio ṣaju mi: Ọlọrun yio jẹ ki emi ri ifẹ mi lara awọn ọta mi.