6 Nwọn pada li aṣalẹ: nwọn npariwo bi ajá, nwọn nrìn yi ilu na ka.
7 Kiyesi i, nwọn nfi ẹnu wọn gùfẹ jade: idà wà li ète wọn: nitoriti nwọn nwipe, tali o gbọ́?
8 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio rẹrin wọn: iwọ ni yio yọṣuti si gbogbo awọn keferi.
9 Agbara rẹ̀ li emi o duro tì: nitori Ọlọrun li àbo mi.
10 Ọlọrun ãnu mi ni yio ṣaju mi: Ọlọrun yio jẹ ki emi ri ifẹ mi lara awọn ọta mi.
11 Máṣe pa wọn, ki awọn enia mi ki o má ba gbagbe: tú wọn ká nipa agbara rẹ; ki o si sọ̀ wọn kalẹ, Oluwa asà wa.
12 Nitori ẹ̀ṣẹ ẹnu wọn ni ọ̀rọ ète wọn, ki a mu wọn ninu igberaga wọn: ati nitori ẽbu ati èke ti nwọn nṣe.