1 OLUWA, máṣe ba mi wi ni ibinu rẹ, ki iwọ ki o má ṣe nà mi ni gbigbona ibinujẹ rẹ.
2 Oluwa, ṣãnu fun mi; nitori ailera mi: Oluwa, mu mi lara da; nitori ti ara kan egungun mi.
3 Ara kan ọkàn mi gogo pẹlu: ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio ti pẹ to!
4 Pada, Oluwa, gbà ọkàn mi: gbà mi là nitori ãnu rẹ.