3 Ara kan ọkàn mi gogo pẹlu: ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio ti pẹ to!
4 Pada, Oluwa, gbà ọkàn mi: gbà mi là nitori ãnu rẹ.
5 Nitoriti kò si iranti rẹ ninu okú: ninu isa okú tani yio dupẹ fun ọ?
6 Agara ikerora mi da mi: li oru gbogbo li emi nmu ẹní mi fó li oju omi; emi fi omije mi rin ibusùn mi.
7 Oju mi bajẹ tan nitori ibinujẹ; o di ogbó tan nitori gbogbo awọn ọta mi.
8 Ẹ lọ kuro lọdọ mi, gbogbo ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ; nitori ti Oluwa gbọ́ ohùn ẹkún mi.
9 Oluwa gbọ́ ẹ̀bẹ mi; Oluwa yio gbà adura mi.