1 ỌLỌRUN nikan li ọkàn mi duro jẹ dè; lati ọdọ rẹ̀ wá ni igbala mi.
2 On nikan li apata mi ati igbala mi; on li àbo mi, emi kì yio ṣipò pada jọjọ.
3 Ẹnyin o ti ma rọlu enia kan pẹ to? gbogbo nyin li o fẹ pa a: bi ogiri ti o bìwó ati bi ọgbà ti nwó lọ.
4 Kiki ìro wọn ni lati já a tilẹ kuro ninu ọlá rẹ̀: nwọn nṣe inu didùn ninu eke: nwọn nfi ẹnu wọn sure, ṣugbọn nwọn ngegun ni inu wọn.