1 ỌLỌRUN, iyìn duro jẹ de ọ ni Sioni: ati si ọ li a o mu ileri ifẹ nì ṣẹ.
2 Iwọ ti ngbọ́ adura, si ọdọ rẹ ni gbogbo enia mbọ̀.
3 Ọ̀ran aiṣedede bori mi: bi o ṣe ti irekọja wa ni, iwọ ni yio wẹ̀ wọn nù kuro.
4 Alabukún-fun li ẹniti iwọ yàn, ti iwọ si mu lati ma sunmọ ọdọ rẹ, ki o le ma gbe inu agbala rẹ wọnni: ore inu ile rẹ yio tẹ́ wa lọrùn, ani ti tempili mimọ́ rẹ.
5 Ohun iyanu nipa ododo ni iwọ fi da wa lohùn, Ọlọrun igbala wa: ẹniti iṣe igbẹkẹle gbogbo opin aiye, ati awọn ti o jina réré si okun.
6 Nipa agbara rẹ̀ ẹniti o fi idi òke nla mulẹ ṣinṣin; ti a fi agbara dì li àmure: