1 KI Ọlọrun ki o ṣãnu fun wa, ki o si busi i fun wa; ki o si ṣe oju rẹ̀ ki o mọlẹ si wa lara,
2 Ki ọ̀na rẹ ki o le di mimọ̀ li aiye, ati igbala ilera rẹ ni gbogbo orilẹ-ède.
3 Jẹ ki awọn enia ki o yìn ọ, Ọlọrun; jẹ ki gbogbo enia ki o yìn ọ.
4 Jẹ ki inu awọn orilẹ-ède ki o dùn, ki nwọn ki o ma kọrin fun ayọ̀: nitoriti iwọ o fi ododo ṣe idajọ enia, iwọ o si jọba awọn orilẹ-ède li aiye.
5 Jẹ ki awọn enia ki o yìn ọ, Ọlọrun; jẹ ki gbogbo enia ki o yìn ọ.