14 Yọ mi kuro ninu ẹrẹ̀, má si ṣe jẹ ki emi ki o rì: gbigbà ni ki a gbà mi lọwọ awọn ti o korira mi, ati ninu omi jijìn wọnni.
15 Máṣe jẹ ki kikún-omi ki o bò mi mọlẹ, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki ọgbun ki o gbé mi mì, ki o má si ṣe jẹ ki iho ki o pa ẹnu rẹ̀ de mọ́ mi.
16 Oluwa, da mi lohùn; nitori ti iṣeun ifẹ rẹ dara, yipada si mi gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ irọnu ãnu rẹ.
17 Ki o má si ṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara iranṣẹ rẹ: emi sa wà ninu ipọnju; yara, da mi lohùn.
18 Sunmọ ọkàn mi, si rà a pada: gbà mi nitori awọn ọta mi.
19 Iwọ ti mọ̀ ẹ̀gan mi ati ìtiju mi, ati alailọla mi: gbogbo awọn ọta mi li o wà niwaju rẹ.
20 Ẹgan ti bà mi ni inu jẹ; emi si kún fun ikãnu: emi si woye fun ẹniti yio ṣãnu fun mi, ṣugbọn kò si; ati fun awọn olutunu, emi kò si ri ẹnikan.