20 Ẹgan ti bà mi ni inu jẹ; emi si kún fun ikãnu: emi si woye fun ẹniti yio ṣãnu fun mi, ṣugbọn kò si; ati fun awọn olutunu, emi kò si ri ẹnikan.
21 Nwọn fi orõro fun mi pẹlu li ohun jijẹ mi; ati li ongbẹ mi nwọn fun mi li ọti kikan ni mimu.
22 Jẹ ki tabili wọn ki o di ikẹkun niwaju wọn: fun awọn ti o wà li alafia, ki o si di okùn didẹ.
23 Jẹ ki oju wọn ki o ṣú, ki nwọn ki o má riran, ki o si ma mu ẹgbẹ́ wọn gbọn nigbagbogbo.
24 Dà irunu rẹ si wọn lori, si jẹ ki ikannu ibinu rẹ ki o le wọn ba.
25 Jẹ ki ibujoko wọn ki o di ahoro; ki ẹnikẹni ki o máṣe gbe inu agọ wọn.
26 Nitori ti nwọn nṣe inunibini si ẹniti iwọ ti lù; nwọn si nsọ̀rọ ibinujẹ ti awọn ti iwọ ti ṣá li ọgbẹ.