23 Jẹ ki oju wọn ki o ṣú, ki nwọn ki o má riran, ki o si ma mu ẹgbẹ́ wọn gbọn nigbagbogbo.
24 Dà irunu rẹ si wọn lori, si jẹ ki ikannu ibinu rẹ ki o le wọn ba.
25 Jẹ ki ibujoko wọn ki o di ahoro; ki ẹnikẹni ki o máṣe gbe inu agọ wọn.
26 Nitori ti nwọn nṣe inunibini si ẹniti iwọ ti lù; nwọn si nsọ̀rọ ibinujẹ ti awọn ti iwọ ti ṣá li ọgbẹ.
27 Fi ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ wọn: ki o má si ṣe jẹ ki nwọn ki o wá sinu ododo rẹ.
28 Nù wọn kuro ninu iwe awọn alãye, ki a má si kọwe wọn pẹlu awọn olododo.
29 Ṣugbọn talaka ati ẹni-ikãnu li emi, Ọlọrun jẹ ki igbala rẹ ki o gbé mi leke.