18 Pẹlupẹlu, nigbati emi di arugbo tan ti mo hewu, Ọlọrun máṣe kọ̀ mi; titi emi o fi fi ipá rẹ hàn fun iran yi, ati agbara rẹ fun gbogbo awọn ara ẹ̀hin.
19 Ọlọrun ododo rẹ ga jọjọ pẹlu, ẹniti o ti nṣe nkan nla: Ọlọrun, tali o dabi iwọ!
20 Iwọ ti o fi iṣẹ nla ati kikan hàn mi, ni yio si tun mi ji, yio si tun mu mi sọ si òke lati ọgbun ilẹ wá.
21 Iwọ o sọ ọlá mi di pupọ̀, iwọ o si tù mi ninu niha gbogbo.
22 Emi o si fi ohun-elo orin yìn ọ pẹlu, ani otitọ rẹ, Ọlọrun mi: iwọ li emi o ma fi duru kọrin si, iwọ Ẹni-Mimọ́ Israeli.
23 Ete mi yio yọ̀ gidigidi, nigbati mo ba nkọrin si ọ: ati ọkàn mi, ti iwọ ti rapada.
24 Ahọn mi pẹlu yio si ma sọ̀rọ ododo rẹ titi li ọjọ gbogbo: nitoriti nwọn dãmu, a si doju ti awọn tí nwá ifarapa mi.