9 Máṣe ṣa mi ti ni ìgba ogbó; máṣe kọ̀ mi silẹ nigbati agbara mi ba yẹ̀.
10 Nitori awọn ọta mi nsọ̀rọ si mi; awọn ti nṣọ ọkàn mi si gbimọ̀ pọ̀.
11 Nwọn wipe, Ọlọrun ti kọ̀ ọ silẹ: ẹ lepa ki ẹ si mu u; nitori ti kò si ẹniti yio gbà a.
12 Ọlọrun, máṣe jina si mi: Ọlọrun mi, yara si iranlọwọ mi.
13 Jẹ ki nwọn ki o dãmu, ki a si run awọn ti nṣe ọta ọkàn mi, ki a si fi ẹ̀gan ati àbuku bo awọn ti nwá ifarapa mi.
14 Ṣugbọn emi o ma reti nigbagbogbo, emi o si ma fi iyìn kún iyìn rẹ.
15 Ẹnu mi yio ma fi ododo rẹ ati igbala rẹ hàn li ọjọ gbogbo; emi kò sa mọ̀ iye rẹ̀.