1 NITÕTỌ Ọlọrun ṣeun fun Israeli, fun iru awọn ti iṣe alaiya mimọ́.
2 Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, ẹsẹ mi fẹrẹ yẹ̀ tan; ìrin mi fẹrẹ yọ́ tan.
3 Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣe-fefe, nigbati mo ri alafia awọn enia buburu.
4 Nitoriti kò si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ̀.
5 Nwọn kò ni ipin ninu iyọnu enia; bẹ̃ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran.