19 Bawo li a ti mu wọn lọ sinu idahoro yi, bi ẹnipe ni iṣẹju kan! ibẹru li a fi nrun wọn patapata.
20 Bi igbati ẹnikan ba ji li oju alá; bẹ̃ni Oluwa, nigbati iwọ ba ji, iwọ o ṣe àbuku àworan wọn.
21 Bayi ni inu mi bajẹ, ẹgún si gun mi li ọkàn mi.
22 Bẹ̃ni mo ṣiwere, ti emi kò si mọ̀ nkan; mo dabi ẹranko niwaju rẹ.
23 Ṣugbọn emi wà pẹlu rẹ nigbagbogbo: iwọ li o ti di ọwọ ọtún mi mu.
24 Iwọ o fi ìmọ rẹ tọ́ mi li ọ̀na, ati nigbẹhin iwọ o gbà mi sinu ogo.
25 Tani mo ni li ọrun bikoṣe iwọ? kò si si ohun ti mo fẹ li aiye pẹlu rẹ.