25 Tani mo ni li ọrun bikoṣe iwọ? kò si si ohun ti mo fẹ li aiye pẹlu rẹ.
26 Ẹran-ara mi ati aiya mi di ãrẹ̀ tan: ṣugbọn Ọlọrun ni apata aiya mi, ati ipin mi lailai.
27 Sa wò o, awọn ti o jina si ọ yio ṣegbe: iwọ ti pa gbogbo wọn run ti nṣe àgbere kiri kuro lọdọ rẹ.
28 Ṣugbọn o dara fun mi lati sunmọ Ọlọrun: emi ti gbẹkẹ mi le Oluwa Ọlọrun, ki emi ki o le ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ gbogbo.