4 Nitoriti kò si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ̀.
5 Nwọn kò ni ipin ninu iyọnu enia; bẹ̃ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran.
6 Nitorina ni igberaga ṣe ká wọn lọrun bi ẹ̀wọn ọṣọ́; ìwa-ipa bò wọn mọlẹ bi aṣọ.
7 Oju wọn yọ jade fun isanra: nwọn ní jù bi ọkàn wọn ti nfẹ lọ.
8 Nwọn nṣẹsin, nwọn si nsọ̀rọ buburu niti inilara: nwọn nsọ̀rọ lati ibi giga.
9 Nwọn gbé ẹnu wọn le ọrun, ahọn wọn si nrìn ilẹ já.
10 Nitorina li awọn enia rẹ̀ ṣe yipada si ihin: ọ̀pọlọpọ omi li a si npọn jade fun wọn.