17 Nwọn si tún ṣẹ̀ si i; ni ṣiṣọtẹ si Ọga-ogo li aginju.
18 Nwọn si dán Ọlọrun wò li ọkàn wọn, ni bibère onjẹ fun ifẹkufẹ wọn.
19 Nwọn si sọ̀rọ si Ọlọrun; nwọn wipe, Ọlọrun ha le tẹ́ tabili li aginju?
20 Wò o! o lù apata, omi si tú jade, iṣàn-omi si kún pupọ; o ha le funni li àkara pẹlu? o ha le pèse ẹran fun awọn enia rẹ̀?
21 Nitorina, Oluwa gbọ́ eyi, o binu: bẹ̃ni iná ràn ni Jakobu, ibinu si ru ni Israeli;
22 Nitori ti nwọn kò gbà Ọlọrun gbọ́, nwọn kò si gbẹkẹle igbala rẹ̀.
23 O paṣẹ fun awọsanma lati òke wá, o si ṣi ilẹkùn ọrun silẹ.