19 Nwọn si sọ̀rọ si Ọlọrun; nwọn wipe, Ọlọrun ha le tẹ́ tabili li aginju?
20 Wò o! o lù apata, omi si tú jade, iṣàn-omi si kún pupọ; o ha le funni li àkara pẹlu? o ha le pèse ẹran fun awọn enia rẹ̀?
21 Nitorina, Oluwa gbọ́ eyi, o binu: bẹ̃ni iná ràn ni Jakobu, ibinu si ru ni Israeli;
22 Nitori ti nwọn kò gbà Ọlọrun gbọ́, nwọn kò si gbẹkẹle igbala rẹ̀.
23 O paṣẹ fun awọsanma lati òke wá, o si ṣi ilẹkùn ọrun silẹ.
24 O si rọ̀jo Manna silẹ fun wọn ni jijẹ, o si fun wọn li ọkà ọrun.
25 Enia jẹ onjẹ awọn angeli; o rán onjẹ si wọn li ajẹyo.