24 O si rọ̀jo Manna silẹ fun wọn ni jijẹ, o si fun wọn li ọkà ọrun.
25 Enia jẹ onjẹ awọn angeli; o rán onjẹ si wọn li ajẹyo.
26 O mu afẹfẹ ìla-õrun fẹ li ọrun, ati nipa agbara rẹ̀ o mu afẹfẹ gusu wá.
27 O rọ̀jo ẹran si wọn pẹlu bi erupẹ ilẹ, ati ẹiyẹ abiyẹ bi iyanrin okun.
28 O si jẹ ki o bọ́ si ãrin ibudo wọn, yi agọ wọn ka.
29 Bẹ̃ni nwọn jẹ, nwọn si yo jọjọ: nitoriti o fi ifẹ wọn fun wọn.
30 Nwọn kò kuro ninu ifẹkufẹ wọn; nigbati onjẹ wọn si wà li ẹnu wọn.