28 O si jẹ ki o bọ́ si ãrin ibudo wọn, yi agọ wọn ka.
29 Bẹ̃ni nwọn jẹ, nwọn si yo jọjọ: nitoriti o fi ifẹ wọn fun wọn.
30 Nwọn kò kuro ninu ifẹkufẹ wọn; nigbati onjẹ wọn si wà li ẹnu wọn.
31 Ibinu Ọlọrun de si ori wọn, o pa awọn ti o sanra ninu wọn, o si lù awọn ọdọmọkunrin Israeli bolẹ.
32 Ninu gbogbo wọnyi nwọn nṣẹ̀ siwaju, nwọn kò si gbà iṣẹ iyanu rẹ̀ gbọ́.
33 Nitorina li o ṣe run ọjọ wọn li asan, ati ọdun wọn ni ijaiya.
34 Nigbati o pa wọn, nigbana ni nwọn wá a kiri: nwọn si pada, nwọn bère Ọlọrun lakokò,