37 Nitori ọkàn wọn kò ṣe dẽde pẹlu rẹ̀, bẹ̃ni nwọn kò si duro ṣinṣin ni majẹmu rẹ̀.
38 Ṣugbọn on, o kún fun iyọ́nu, o fi ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn, kò si run wọn: nitõtọ, nigba pupọ̀ li o yi ibinu rẹ̀ pada, ti kò si ru gbogbo ibinu rẹ̀ soke.
39 Nitoriti o ranti pe, enia ṣa ni nwọn; afẹfẹ ti nkọja lọ, ti kò si tun pada wá mọ.
40 Igba melo-melo ni nwọn sọ̀tẹ si i li aginju, ti nwọn si bà a ninu jẹ ninu aṣálẹ!
41 Nitõtọ, nwọn yipada, nwọn si dan Ọlọrun wò, nwọn si ṣe aropin Ẹni-Mimọ́ Israeli.
42 Nwọn kò ranti ọwọ rẹ̀, tabi ọjọ nì ti o gbà wọn lọwọ ọta.
43 Bi o ti ṣe iṣẹ-àmi rẹ̀ ni Egipti, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ni igbẹ Soani.