45 O rán eṣinṣin sinu wọn, ti o jẹ wọn; ati ọpọlọ, ti o run wọn.
46 O fi eso ilẹ wọn fun kokoro pẹlu, ati iṣẹ wọn fun ẽṣú.
47 O fi yinyin pa àjara wọn, o si fi yinyin nla pa igi sikamore wọn.
48 O fi ohun ọ̀sin wọn pẹlu fun yinyin, ati agbo-ẹran wọn fun manamana.
49 O mu kikoro ibinu rẹ̀ wá si wọn lara, irunu ati ikannu, ati ipọnju, nipa riran angeli ibi sinu wọn.
50 O ṣina silẹ fun ibinu rẹ̀; kò da ọkàn wọn si lọwọ ikú, ṣugbọn o fi ẹmi wọn fun àjakalẹ-àrun.
51 O si kọlu gbogbo awọn akọbi ni Egipti, olori agbara wọn ninu agọ Hamu: