49 O mu kikoro ibinu rẹ̀ wá si wọn lara, irunu ati ikannu, ati ipọnju, nipa riran angeli ibi sinu wọn.
50 O ṣina silẹ fun ibinu rẹ̀; kò da ọkàn wọn si lọwọ ikú, ṣugbọn o fi ẹmi wọn fun àjakalẹ-àrun.
51 O si kọlu gbogbo awọn akọbi ni Egipti, olori agbara wọn ninu agọ Hamu:
52 Ṣugbọn o mu awọn enia tirẹ̀ lọ bi agutan, o si ṣe itọju wọn ni iju bi agbo-ẹran.
53 O si ṣe amọna wọn li alafia, bẹ̃ni nwọn kò si bẹ̀ru: ṣugbọn okun bò awọn ọta wọn mọlẹ.
54 O si mu wọn wá si eti ibi-mimọ́ rẹ̀, ani si òke yi ti ọwọ ọtún rẹ̀ ti rà.
55 O tì awọn keferi jade pẹlu kuro niwaju wọn, o si fi tita okùn pinlẹ fun wọn ni ilẹ-ini, o si mu awọn ẹya Israeli joko ninu agọ wọn.