57 Ṣugbọn nwọn yipada, nwọn ṣe alaiṣotitọ bi awọn baba wọn: nwọn si pẹhinda si apakan bi ọrun ẹ̀tan.
58 Nitori ti nwọn fi ibi giga wọn bi i ninu, nwọn si fi ere finfin wọn mu u jowu.
59 Nigbati Ọlọrun gbọ́ eyi, o binu, o si korira Israeli gidigidi.
60 Bẹ̃li o kọ̀ agọ Ṣilo silẹ, agọ ti o pa ninu awọn enia.
61 O si fi agbara rẹ̀ fun igbekun, ati ogo rẹ̀ le ọwọ ọta nì.
62 O fi awọn enia rẹ̀ fun idà pẹlu; o si binu si ilẹ-ini rẹ̀.
63 Iná run awọn ọdọmọkunrin wọn; a kò si fi orin sin awọn wundia wọn ni iyawo.