64 Awọn alufa wọn ti oju idà ṣubu; awọn opó wọn kò si pohunrere ẹkún.
65 Nigbana li Oluwa ji bi ẹnipe loju orun, ati bi alagbara ti o nkọ nitori ọti-waini.
66 O si kọlu awọn ọta rẹ̀ lẹhin; o sọ wọn di ẹ̀gan titi aiye.
67 Pẹlupẹlu o kọ̀ agọ Josefu, kò si yàn ẹ̀ya Efraimu:
68 Ṣugbọn o yan ẹ̀ya Juda, òke Sioni ti o fẹ.
69 O si kọ́ ibi-mimọ́ rẹ̀ bi òke-ọrun bi ilẹ ti o ti fi idi rẹ̀ mulẹ lailai.
70 O si yàn Dafidi iranṣẹ rẹ̀, o si mu u kuro lati inu agbo-agutan wá: