6 Dà ibinu rẹ si ori awọn keferi ti kò mọ̀ ọ, ati si ori awọn ijọba ti kò kepè orukọ rẹ.
7 Nitori ti nwọn ti mu Jakobu jẹ, nwọn si sọ ibujoko rẹ̀ di ahoro.
8 Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ awọn aṣaju wa si wa: jẹ ki iyọnu rẹ ki o ṣaju wa nisisiyi: nitori ti a rẹ̀ wa silẹ gidigidi.
9 Ràn wa lọwọ, Ọlọrun igbala wa, nitori ogo orukọ rẹ: ki o si gbà wa, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ wa nù, nitori orukọ rẹ.
10 Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà? jẹ ki a mọ̀ igbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ ti a ta silẹ loju wa ninu awọn keferi.
11 Jẹ ki imi-ẹdun onde nì ki o wá siwaju rẹ: gẹgẹ bi titobi agbara rẹ, iwọ dá awọn ti a yàn si pipa silẹ:
12 Ki o si san ẹ̀gan wọn nigba meje fun awọn aladugbo wa li aiya wọn, nipa eyiti nwọn ngàn ọ, Oluwa.